top of page
Search

Ìdí tí ìjọba fí pa Fred Hampton (Why the government assassinated Fred Hampton)

Updated: Feb 28, 2023

Ki ni ẹgbẹ́ ẹkùn dúdú?

What is the Black Panther Party?


Ni ọdún 1966, Huey P. Newton àti Bobby Seale dá ẹgbẹ́ ẹkùn dúdú sílẹ̀ ní ìlú Oakland láti gbógun ti ìrorò àwọn ọlọ́pàá àti níni àwọn adúláwọ̀ lara.


In the year 1966, Huey P. Newton and Bobby Seale founded the Black panther Party to combat police brutality and oppression of black people.


Black Panther Party founders Bobby Seale and Huey P. Newton.

Ẹgbẹ́ ẹkùn dúdú lo ìlànà ìwé kan tí wọ́n pè ní "ètò onikókó mẹ́wàá". Ìwé yìí sọ̀rọ̀ nípa bí a ṣe lè fòpin sí bí àwọn ọlọ́pàá ṣe n pa àdúláwọ̀, Ó sì sọ̀rọ̀ nípa, oúnjẹ, aṣọ, ilé gbígbé, àti ilẹ̀ fún àwọn aláwọ̀ dúdú.


The Black Panther Party used a guiding document they called the ten point program. This document talked about ending police killings of black people. It also talked about food, clothes, housing, and land for black people.


Nígbà tí o máa fi di ọdún 1970, wọ́n ti wà nílú káàkiri Amẹ́ríkà, bi àpẹẹrẹ ìlú Los Angeles, Chicago, New York, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.


By the 1970s, the Black Panther Party was in cities around the country, i.e., Los Angeles, Chicago, New York, etc.


Isẹ́ ti ẹgbẹ́ ẹkùn dúdú ṣe ni bí ètò oúnjẹ àárọ̀ ọ́fẹ̀ẹ́, ilé ìwòsàn ọ́fẹ̀ẹ́, ilé ẹ̀kọ́ ọ́fẹ̀ẹ́, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.


The work of the Black Panther Party included the free breakfast program, free clinic, free schools, etc.


Panthers serving children free breakfast, Sacred Heart Church, San Francisco Photo by Ducho Dennis, Courtesy It’s About Time Archive

Ilé iṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ FBI (Federal Bureau of Investigation) ti Amerika ṣọ́ ẹgbẹ́ ẹkùn dúdú lójú méjèèjì. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni wọ́n sì fòòró ẹ̀mí wọ́n.


The FBI watched the Black Panther Party closely and harassed them constantly.


Ta ni Fred Hampton?

Who was Fred Hampton?


Kí ló dé tí Fred Hampton fí jẹ́ ewu fún ìjọba Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà?

What made him a threat to the American government?


Fred Hampton ni alága ẹgbẹ́ ẹkùn dúdú ìlú Chicago. Olùbánisọ̀rọ̀ ati olùṣètò to dara ju ni Fred Hampton.


Fred Hampton was the chairman of the Chicago Black Panther Party. He was a master speaker and organizer.


Chairman Fred Hampton

Láfikún sí isẹ́ ẹgbẹ́ ẹkùn dúdú, Fred Hampton dá ẹgbẹ́ tí a n pe ni ẹgbẹ́ Òṣùmàrè. Ó so orísirísi ìran pọ̀ lábẹ́ ẹgbẹ́ yìí, bi àpẹẹrẹ àwọn talakà aláwọ̀ funfun, àwọn ọmọ Puerto Rico, àwọn ẹgbẹ́ ọmọọ̀ta aláwọ̀ dudu ìlú Chicago, ati bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.


In addition to the Black Panther Party work, Fred Hampton created a group called the rainbow coalition.

He united various races under the coalition, i.e., poor whites, Puerto Ricans, black Chicago gangs, etc.


Fred Hampton mọ̀ pé bí àwọn èèyàn tí a ń ni lára ba para pọ̀, wọ́n máa ní ágbára jù èèyàn kọ̀ọ̀kan lọ. Wọ́n sì lè borí ìwà ikà ìjọba.


Fred Hampton understood that if oppressed people united, they would be more powerful and could challenge the oppression of the government.


Èyí ló mú Ilé iṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ FBI rí i gẹ́gẹ́ bí ewu ńlá.


This made him a major threat to the FBI.


Ní ọjọ́ kẹrin, oṣù kejìlá, ọdún 1969, àwọn FBI àti àwọn ọlọ́pàá para pọ̀ láti pá Fred Hampton. Ní ọ̀gànjọ́ òru, àwọn ọlọ́pàá já ilẹ̀kùn ilé rẹ̀. Wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí yìnbọn. Wọn yin ọta ìbọn tó ju àádọ́rùn-ún lọ sí inú ilé rẹ. Wọn sì pa Fred Hampton nígbà tó wà lórí ibùsùn pẹlu iyawo rẹ.


On December 4th, 1969, the FBI and the police collaborated to assassinate Fred Hampton. In the middle of the night, the police broke down the door and started shooting. They fired more than 90 shots into his house, killing Fred Hampton while he lay in bed with his wife.


The bedroom in which Fred Hampton was killed while laying with his pregnant wife at 2337 W. Monroe St. on Dec. 4, 1969.

About the author:

I am a black person from the diaspora who is learning the Yorùbá language to reconnect with my ancestors and decolonize my mind. This is the first of many such writings.139 views0 comments

Comments


bottom of page